Isaiah 63:1-6

Ọjọ́ ẹ̀san àti ìràpadà Ọlọ́run

1 aTa nì eléyìí tí ó Edomu wá,
ti òun ti aṣọ àrẹpọ́n láti Bosra wá?
Ta nì eléyìí, tí ó ní ògo nínú aṣọ rẹ̀,
tí ó ń yan bọ̀ wá nínú ọláńlá agbára rẹ̀?

“Èmi ni ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ nínú òdodo
tí ó ní ipa láti gbàlà.”

2Èéṣe tí aṣọ yín fi pupa
gẹ́gẹ́ bí i tàwọn tí ń ṣiṣẹ́ ní ìfúntí?

3 b“Èmi nìkan ti dá tẹ ìfúntí wáìnì;
láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹnikẹ́ni kò sì wà pẹ̀lú mi.
Mo tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ ní ìbínú mi
mo sì tẹ̀ wọ́n rẹ́ ní ìrunú mi
ẹ̀jẹ̀ wọn sì fọ́n sí aṣọ mi,
mo sì da àbàwọ́n sí gbogbo aṣọ mi.
4Nítorí ọjọ́ ẹ̀san wà ní ọkàn mi
àti pé ọdún ìràpadà mi ti dé
5Mo wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti ṣe ìrànwọ́.
Àyà fò mí pé ẹnikẹ́ni kò ṣèrànwọ́;
nítorí náà apá mi ni ó ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún mi
àti ìrunú mi ni ó gbé mi ró.
6Mo tẹ orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀ nínú ìbínú mi;
nínú ìrunú mi mo jẹ́ kí wọ́n mu
mo sì da ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ lórí erùpẹ̀.”
Copyright information for YorBMYO